Перейти к содержимому

Orin Ojowubinrin by Ogundare Foyanmu | ODEC 47

Dundun

0:00 / 0:00

Orin Ojowubinrin by Ogundare Foyanmu | ODEC 47

8 167 просмотров · 5 лет назад
Dundun
15,1 тыс. подписчиков
8 167 просмотров · 5 лет назад
Nínú àwo rẹ́kọ́ọ́dù yí ni ọ̀jọ̀gbọ́n Ogundare Foyanmu tí kọrin lórí àwọn wọ̀nyí: JAGUNJAGUN BẸNJAMẸ́Ẹ́NÌ ADÉKÚNLÉ ORIN ÒJÒWÚ OBÌNRIN Ọ̀RẸ́ Ọ̀DÀLẸ̀ Awítúnwí akùdé gbólóhùn jẹyọ nínú ewì Ọ̀RẸ́ Ọ̀DÀLẸ̀. Níbẹ̀ ni Foyanmu ti ṣàpẹẹrẹ ìwà àwọn ènìyàn kan láwùjọ, tí ìlú yóò lérò láti gbé wọn sípò tó ga, ṣùgbọ́n tó jẹ́ pé ìwà tí irú nnkan bẹ́ẹ̀ yóò se fò wọ́n ru ni wọ́n máa hù. "À lá á fewúrẹ́ joyè, ewúrẹ́ ń jewé ọdán À lá á fàgùtàn joyè, wọ́n à si maa jẹ ìyẹ̀fù À lá á f'ológínní joyè òkè, àjà ní n fò fẹrẹ" Ogundare Ayano, ọmọ wọn ní Ilé Foyanmu, Taràá, Ogbomoso gbé ki Jagunjagun Bẹ́ńjámínì Adekunle tí òun náà jẹ́ ọmọ Ogbomoso ṣùgbọ́n ó ti di olóògbé báyìí. Ogundare Foyanmu nínú ká fi ewì ṣe àpọ́nlé ènìyàn, ó ṣe àpọ́nlé Ajagunfẹ̀yìntì BẸNJAMẸẸNI ADEKUNLE púpọ̀ gbáà. Pàápàá jù lọ bí ó ṣe jagun gba Nàìjíríà sílẹ̀ lọ́wọ́ ogun Biafra tí Ojúku gbé dìde. Bí ẹ bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa Ogundare Foyanmu àti àwọn orin Ìjálá tó ti kọ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ wọn, ẹ ríi pé ẹ ra ìwé tí 'ṢAYỌ̀ ALÁGBÈ kọ tí a pè ní ÌJÁLÁ OGUNDARE FOYANMU (ÌJÌNLẸ̀ ÈDÈ OHÙN ẸNU YORÙBÁ). For more information about Ogundare Foyanmu and insight into his Aré Ìjálá Ọdẹ, buy the book written by 'ṢAYỌ̀ ALÁGBÈ called ÌJÁLÁ OGÚNDÁRE FỌ́YÁNMU (ÌJÌNLẸ̀ ÈDÈ OHÙN ẸNU YORÙBÁ). #ijala #ogbomoso #ogundarefoyanmu